Àarę FICT, Àarę NAMACOS kédùn lori Ìpàdánù Àdùfé ti o Ję Ọmọ Ile-èkó Gbogbonise ti Ilu Iree

By: Afeez Ogungbemi, Boluwaji Daso



Olọlá Alabetutu Korede ti o je Aare ti eto iroyin ati imọ-ẹrọ ibaraẹnisọrọ (FICT) ti ile èkó gbogbonise, ilu Iree ni Ipinle Osun ti fi ibanuje okan ati okan kedun lori iku airotele ti o mu omo ile iwe Obinrin, Adufe Kehinde, jade laye lẹhin aisan diẹ. 


Oro itunu re wa ninu atejade kan ti akoroyin NEB gbe jade lonii, Satide, Ogún ojo, osu kejo odun 2023, ti Aare naa fowo si. Adufe Kehinde, ti o je ọmọ ile-iwe Diploma Orílẹ-èdè ti o ṣe pataki ni Ẹka Ibaraẹnisọrọ (Mass Communication), ni awon eniyan mọ jakejado fun awọn aṣeyọri alailẹgbẹ rẹ ni ogba ati laarin agbegbe rẹ. 


Ari gbo wipe odomode-binrin naa jokoo fun idanwo lojo Abameta, (Satide), ojo kokandinlogun osu kejo odun 2023 (ni ana) Sugbon won gbe lo si ilu re lojo naa lati gba itoju to peye fun aisan re, ti o si mu ki awon araalu ati awon akeko ile-iwe gbogbonise naa wa ninu ibanuje gege bi ololá Akorede, ti o je asiwaji fun awon akeko FICT naa fi Ibanujẹ okan kẹdun si awọn ẹbi ati awọn ọrẹ oloogbe naa lapapọ. 


Sibẹsibẹ, Aare Èka ibaraenisoro ti a mo si NAMACOS, Part Time (DPT), Iree, Oladeji Israel Victor ninu atẹjade kan ti o fi han fun gbogbo eniyan ati ti awọn alaṣẹ NAMACOS fowo si so wipe, Ibanujẹ nla ni iku Adufe je fun awon akeegbe re pelu awon obi re gege bi o se fi itunu ọkan re han si awọn ẹbi ati awọn ọrẹ rẹ.

Comments

Popular posts from this blog

Tragic Auto Crash Claims Life of Prominent Mass Communication Student at Osun State Polytechnic, Iree

OSPOLY MGT DIRECTS STUDENT TO PAY THEIR SCHOOL FEES

OSPOLY Mgt Schedules Date for DPT Third Semester Examination, Urges Students To Pay School Fees